Àkòrí Ìpàdé:
“ÌṢÀKÓSO ÀÀBÒ KÁÀKIRI ILẸ̀ ÒGBÓMÒSÓ: ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ TÓ JEYO, ÀWỌN ÌPENIJA ÀTI

ÀǸFÀÀNÍ OJÓ IWÁJÚ”
Èyí tó wáyé ní: The Great Hall, LAUTECH, Ògbómọ̀ṣó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ogbònjó Oṣù Kẹsàn-án, odún 2026
ÌBẸ̀RẸ̀
Ìpàdé Ààbò llè Ògbómọ̀ṣó ti odún yíí, (2026) wáyé lábẹ́ àbójútó Ìran olódún márúndílógbòn (25 years
agenda) fún Ìdàgbàsókè ilè Ògbómọ̀ṣó, tí olólá, Obá onípò gíga, Kabiyesi Ọba Ghandi Afolabi Olaoye
Orumogege kèta, Sọ̀ún ilè Ògbómọ̀ṣó gbé kalẹ̀. Ìpàdé náà kó àwọn alákóso àṣà ìbílẹ̀, aṣojú ìjọba, àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò, àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ gíga, aṣáájú àwùjọ, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, àwọn ẹgbẹ́ awùjọ àti àwọn olùkópa pàtàkì mìíràn jọ. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ó lé ní ogójì (40) àwọn Ọba àti àwọn alákóso ìbílẹ̀ láti oríṣìíríṣìí agbègbè ilè Ògbómọ̀ṣó ni wón péjú pésè níbi ìpàdé náà, èyí tó fi hàn pé àwọn Ọba àti àwọn aṣáájú àṣà ti pinnu láti ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ààbò àti àlàáfíà ilẹ̀ Ogbomoso.
Àwọn èróngbà ati ìdí abájo pàtàkì ìpàdé náà ni:
• Láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ìṣòro ààbò tó ń dojú kọ ilè Ògbómọ̀ṣó lówólówó báyìí àti àwọn èyítí tí ó lè farahàn lọ́jọ́ iwájú.
• Láti gbé ètò ààbò tí àwọn aráàlú fúnra wọn yóò ní ipa pàtàkì nínú rẹ̀ kalẹ̀.
• Láti gbé ètò ìkówójo owó ààbò fún ilè Ògbómọ̀ṣó sílẹ̀, èyítí ó le tó fún ìpèsè àwọn ohun èlò àwon nkan ààbò jọ fún iṣẹ́ ààbò, ìpèsè ohun èlò ìrànwọ́ àti nípa síse alamí lórí àkójọpọ̀ ìròyìn nípa ààbò.
• Láti yí ètò ààbò padà láti inú ìdáhùn sí ìṣòro, papaa jùlo lórí irú ìgbésè tó gúnmó lórí ìsèlè tó bá fé ṣẹlẹ̀ ati bí a ó se ìdènà rẹ̀, kí ó tó ṣẹlẹ̀.
• Láti jẹ́ kí ààbò ẹ̀mí àti ohun-ìní di nkan ìpìlẹ̀ fún ìmúṣẹ Ìran olodun 0marundinlogbon fún Ìdàgbàsókè ilè Ògbómọ̀ṣó.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ pàtàkì tí a gbé kalẹ̀, àwọn ìfihàn àti àáyeé láti òdò àwọn onímọ̀, ìjíròrò àwọn agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti àwọn àfikún ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìpàdé náà ṣe àwọn àkíyèsí àti ìpinnu wọ̀nyí:
ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ ÀTI ÌPÌNNU
1. ÀÀBÒ ÈMÍ GÉGÉBÍ ÒPÁKÙTÈLÈ ÌDÀGBÀSÓKÈ
Ìpàdé náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ààbò ẹ̀mí àti ohun-ìní jẹ́ ìpìlè rere fún gbogbo ètò ìdàgbàsókè ilè Ògbómọ̀ṣó. Gẹ́gẹ́ bí Kabiyesi Sọ̀ún ile Ògbómọ̀ṣó ṣe tẹnu mọ́ ọn:
“A gbọ́dọ̀ mú èètò ààbò lórí ilè Ògbómọ̀ṣó lókúnkúndùn, kí ilè Ògbómọ̀ṣó lè dàgbàsókè.”
Nítorí náà, ààbò gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí a máa gbé yẹ̀wò nínú ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé, ètò ẹ̀kọ́, iṣẹ́ àgbẹ̀, òwò síse, ètò ìrìnàjò àti àlàáfíà àwọn aráàlú.
2. ÌSÀKÓSO ÀWỌN ỌBA, ÌṢÒKAN ÀTI IFỌ ̀ KÀNSÌN
Ìpàdé náà dúpẹ́ gidigidi fún ìfarahàn àti ìkópa àwọn Ọba tó lé ní ogójì láti gbogbo agbègbè ilè Ògbómọ̀ṣó. Ìpinnu wáyé wipé ìṣòkan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn Ọba jẹ́ ohun pàtàkì fún àlàáfíà, ààbò àti
ìbágbépọ̀ rere ará ìlú. Àwọn Ọba gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ pọ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aṣáájú nínú fífi ìmọ̀ ààbò sílẹ̀ ní ìpìlẹ̀ ati àwùjọ.
3. ÀÀBÒ JẸ́ OJÚSE GBOGBO WA
Ìpàdé náà gbà pé ìpèsè ààbò kò yẹ kí o jé ojúṣe ìjọba àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò nìkan.
Ó gbódò jẹ́ ojúṣe gbogbo ará ìlú. Ó yẹ kí ó dá lórí: ìkópa àwọn aráàlú; ìfọwọ́sowọ́pọ̀; yíyanjú ìṣòro ní ìpele àwùjọ; àti jíjẹ́wọ́ ojúṣe ara wa.
4. ÌRÒYÌN ÀÀBÒ TÓ PÉ, TÓ YÁ, ÈYÍ TÓ LU KÁLÉ, KÁ OKO, TÍ Ó SÌ DÉÉDÉÉ ÀKÓKÒ
Ìpàdé náà tẹnu mọ́ pàtàkì ìṣọ́ra, ìkójọpọ̀ ìròyìn àti ìmúlò ìròyìn tó péye láti lè mọ̀ nipa ewu kí ó tó di ìṣòro ńlá.
A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn aráàlú bí wọ́n ṣe lè mọ ìwà ti a kii ṣe gbésè tí kò bófin mu, kí wọ́n sì máa fi irú ìròyìn tó bá jẹ́ òtítọ́ ránṣẹ́ kíákíá.
A tún ṣàlàyé pé fífi ìròyìn ààbò ránṣẹ́ kò yẹ kí ó jẹ́ ti Ọlọ́pàá tàbí àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò nìkan. Aráàlú lè fi irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ tó ṣe kókó ránṣẹ́ sí: àwọn aláṣẹ Ìjọba Ìbílẹ̀; àwọn Ọba àti Baálẹ̀; àwọn aṣáájú ẹ̀sìn; àti àwọn aṣáájú àwùjọ tí àwọn ènìyàn gbẹ́kẹ̀ lé.
A gbọ́dọ̀ se àmúlò ìmọ̀ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn fúnra wọn (Human Intelligence – HUMINT) dáadáa.
Kí a fi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó ṣẹlẹ̀ ní ijoba ìbílè Òrìire ṣe àpẹẹrẹ, ìpàdé náà gba ìlànà pàtàkì kan pé:
“A kò gbọ́dọ̀ dúró de kí irú ìsèlè ijoba ibile Òrìire mìíràn wáyé.”
5. ÌDÁGBÀSÓKÈ ÀWỌN ÌGBÌMỌ́ ÀÀBÒ NÍ ÀWON ÌPELE ÌPELE
Ìpàdé náà pàṣẹ pé kí a dá àwọn Ìgbìmọ́ Ààbò sílẹ̀, kí a sì fún àwọn tí ó ti wà ní ìrónilágbára tí ó lókun ní gbogbo ìpele: agbègbè; Ìjọba Ìbílẹ̀; Wọ́ọ̀dù; àwùjọ; àti abúlé.
Àwọn ìgbìmọ́ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ní àwọn Ọba, àwọn aṣáájú àwùjọ, olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́, oníṣòwò, ọdọ́, aṣáájúẹ̀sìn àti àwọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ààbò ninu. Èyí yóò mú kí ìkójọpọ̀ ìròyìn, ìkìlọ̀ ṣáájú ewu àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò rọrùn.
6. OJÚṢE ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀, ÌFỌ ̀ KÀNSÌN PẸ̀LÚ ÌJỌBA ÌPÍN KÀN ÀTI ÀGBÓYÉ ÀWỌN ARÁÀLÚ
Ìpàdé náà tẹnu mọ́ ipa pàtàkì tí Ìjọba Ìbílẹ̀ ní nínú ààbò ní ìpìlẹ̀.
Ìpàdé náà ṣàkíyèsí pẹ̀lú àníyàn pé àìsí àwọn Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ níbi ìpàdé ààbò pàtàkì yìí jẹ́ ohun tí kò bójúmu pẹ̀lú ojúṣe wọn, nítorí pé ó yẹ kí aṣáájú Ìjọba Ìbílẹ̀ wà ní iwájú nínú ọ̀rọ̀ ààbò àwọn aráàlú.
A tún tẹnu mọ́ ìbáṣepọ̀ tó yẹ láàárín Ìjọba Ìbílẹ̀ àti Ìjọba Ìpínlẹ̀ àti ti Àpapọ̀, kí àwọn ohun amáyédẹrùn, iṣẹ́ ìjọba, àwọn ohun ìrànwọ́ àwùjọ àti àǹfààní ọrọ̀ ajé lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn.
Ìjọba rere ní ìpìlẹ̀ yóò mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn aráàlú pọ̀ sí i.
7. ÌMỌ ̀ ÀGBÈGBÈ ÀTI ÀṢÀ ÀÀBÒ ÀWÙJỌ
Ìpàdé náà gba ìmúlò ìmọ̀ àgbègbè, àwọn ọ̀nà ààbò ìbílẹ̀ àti àwọn ètò ààbò tó bófin mu tí àwùjọ fúnra rẹ̀ ń lò. Ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà lábẹ́ òfin, kí a sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ènìyàn.
8. ÒGBÓMỌ ̀ ṢÓ GẸ́GẸ́ BÍ ÀGBÈGBÈ ÀÀBÒ PÀTÀKÌ
Ìpàdé náà gbà pé ipò Ògbómọ̀ṣó jẹ́ pàtàkì nítorí pé ó jẹ́ ọ̀nà àgbélébùú tó so apá Àríwá àti Gúúsù- Ìwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà pọ̀. Nítorí náà, ìṣòro ààbò ní Ògbómọ̀ṣó lè ní nipa dídá kọjá ilè Ògbómọ̀ṣó.
A gbọ́dọ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ààbò pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ àti àwọn Ìjọba Ìbílẹ̀ tó yí Ògbómọ̀ṣó ká.
9. ÀWÒRÁN ÀGBÈGBÈ ÀTI OHUN AMÁYÉDẸRÙN FÚN ÀÀBÒ
Ìpàdé náà dábàá pé kí a ṣe àwòrán àti ìṣàwárí àwọn: àwùjọ; ọ̀nà jíjìn àti ọ̀nà abẹ́lẹ̀; àwọn ibi tí ènìyàn ti ń wọ̀lé àti jáde; ibi ìbánisọ̀rọ̀; iná ìgboro; àti àwọn ibi tí ewu ti lè pọ̀ sí. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ibi tí ewu ti lè wá, kí ìrànwọ́ pajawiri sì lè dé ní kíákíá.
10. KÍ ÌGBẸ́KẸ̀LÉ LÁÀRÍN ÀWỌN ARÁÀLÚ ÀTI ÀWỌN ILÉ-IṢẸ́ ÀÀBÒ LÈ LÓKUN
* Síse àkójopò àti ojúse tó gúnmó lorí níná owó ààbò: kí á ké pe àwọn omo bíbí ìlú Ogbomoso àti àwon olùdóko – òwò káàkiri àgbáyé lati se ìdáwó sinu àsùnwòn ètò ààbò, èyítí ìsàkóso rè a nípon, tó kún fún ìfihàn tó mó gaara, èyítí ó kún ojú òsùnwòn àti àgbékalè ofin tó ní ìkìmí, nípàse àjo àwon olùdarí ati ìgbìmò tó n se kòkárí isé.
Ìpàdé náà pè fún ìgbésẹ̀ tó là kedere láti kọ́ nípa ìgbẹ́kẹ̀lé láàárín àwọn aráàlú àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò.
Ìlànà pé: “Tí a bá rí ohun tí kò tọ́, kí a sọ ọ́.” gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ètò tó máa dá àṣírí àti ààbò ẹni tó bá fúnni ní ìròyìn dúró.
Àwọn Ọba, Baálẹ̀, aṣáájú ẹ̀sìn àti àwọn aláṣẹ Ìjọba Ìbílẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí àwọn aráàlú lè gbà fi ìròyìn ààbò ránṣẹ́.
11. ÀTÌLẸ́YÌN FÚN OWÓ ÌDÁBÒ BÒ ILÈ ÒGBÓMỌṢÓ
Ìpàdé náà lu ìgbékalẹ̀ Owó Ìdábò bò nípa ààbò ilè Ògbómọ̀ṣó lógo enu, wón si tún se sàdánkátà, nítorí pé kíkó owó naa jo jẹ́ ọ̀nà pàtàkì fún kíkó àwọn ohun àmúlò àti owó jọ fún iṣẹ́ ààbò.
A gbọ́dọ̀ lò ó fún: ohun èlò iṣẹ́; ọkọ̀ àti ìrànwọ́ ìrìnàjò; ohun èlò ààbò; àti àwọn amáyédẹrùn ìkójọpọ̀ ìròyìn.
Ìpàdé náà pè sí ìṣàkóso tó hàn gbangba, jíjẹ́wọ́ ojúṣe àti fífi àbájáde iṣẹ́ hàn gbangba.
Gbogbo ọmọ Ògbómọ̀ṣó, tó wà nílé àti tó wà ní òkè-òkun, àwọn ilé-iṣẹ́ àti àwọn olùfẹ́ Ògbómọ̀ṣó ni a ké sí láti kópa.
12. Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ỌMỌDE ÀTI Ọ ̀ DỌ́, ÀTI ÀÀBÒ ILÉ-Ẹ̀KỌ́
Ìpàdé náà tẹnu mọ́ pé ẹ̀kọ́ tó dára, ìtọ́sọ́nà rere àti kíkó ọgbọ́n iṣẹ́ sínú àwọn ọmọde àti ọdọ́ jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àlàáfíà pípẹ́ àti dídín ìwà ọ̀daràn kù.
Ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọde àti ọdọ́ wà ní ilé-ẹ̀kọ́, kí wọ́n sì ní ohun tó ń mú kí wọ́n ṣiṣẹ́ dáadáa níkáwó won, kí wọn má bà a lọ sínú ìwà ọ̀daràn.
Ìpàdé náà tún kí Police Community Relations Committee (PCRC) Schools Initiative káàbọ̀, tí Kabiyesi Sọ̀ún ile Ògbómọ̀ṣó sì ti téwó gba ipò Patron Àgbà won (Grand Patron).
Ètò náà wà láti kọ́ ìmọ̀ ààbò àti ojúṣe ọmọ orílẹ̀-èdè rere sínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
13. TÍTÚMÒ GBOGBO ÀKÓJỌPỌ ̀ ÌPÀDÈ SÍ ÈDÈ YORÙBÁ
Láti jẹ́ kí gbogbo ènìyàn lóye ohun tí a jíròrò lé lórí, kí ìkópa àwọn aráàlú le pọ̀ sí i, kí àwọn ènìyàn sì ní ìmọ̀lára pé wọ́n ní ohun tí ó jẹ́ tiwọn nínú ètò ààbò, ìpàdé náà pinnu pé gbogbo àwọn ìfihàn tí àwọn amòye ṣe àti Ìkédé yìí gbọ́dọ̀ wà ní èdè Yorùbá pẹ̀lú.
Èyí yóò jẹ́ kí àwọn ìlànà àti ìpinnu ààbò lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn ní ilè Ògbómọ̀ṣó.
ÀWỌN ÀBÁ ÀTI ÌṢẸ́ ÀMÚSE TÍ A GBỌ́DỌ ̀ ṢE
1. Dídá Ìgbìmọ́ Ààbò sílẹ̀ ní gbogbo ìpele – agbègbè, Ìjọba Ìbílẹ̀, Wọ́ọ̀dù, àwùjọ àti abúlé.
2. Mímú kí ètò fífi ìròyìn ààbò ránṣẹ́ ṣiṣẹ́ dáadáa – kí ìròyìn tó péye àti tó yá kiakialè dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́pàá, àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò, àwọn aláṣẹ Ìjọba Ìbílẹ̀, Ọba, Baálẹ̀ àti aṣáájú ẹ̀sìn.
3. Mimú ìṣòkan àwọn Ọba àti àwọn aṣáájú ìbílẹ̀ lágbára – kí wọ́n máa bá ara wọn sọ̀rọ̀, ṣiṣẹ́ pọ̀, kí wọ́n sì máa bójú tó ààbò àwọn agbègbè wọn.
4. Mimú ojúṣe Ìjọba Ìbílẹ̀ lágbára – kí àwọn aláṣẹ Ìjọba Ìbílẹ̀ kópa ní kíkún nínú ọ̀rọ̀ ààbò àti ìdàgbàsókè àwùjọ.
5. Fifi ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ ààbò àwọn ọmọde àti ọdọ́ sí ipò pàtàkì – kí wọ́n lè ní ọjọ́ iwájú tó dára, kí ìfarapa sí ìwà ọ̀daràn sì dín kù.
6. Mú kí ìtúmọ̀ Yorùbá jẹ́ apá pàtàkì nínú àwọn àbájáde ìpàdé – kí gbogbo ènìyàn lè lóye àwọn ìpinnu àti ìlànà.
7. Didá “Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ààbò Pẹ̀lú Àwọn Aládùúgbò” sílẹ̀ – kí ile Ògbómọ̀ṣó lè ní ìbáṣepọ̀ ààbò pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ àti agbègbè tó yí i ká.
8. Ṣise àwòrán ààbò gbogbo agbègbè – pẹ̀lú àwọn ọ̀nà pàtàkì, ibi tí ènìyàn ti ń wọ̀ àti jáde, amáyédẹrùn àti àwọn ibi tí ewu ti lè pọ̀ sí.
9. Mimú àwọn ètò ààbò ìbílẹ̀ tó bófin mu wá sínú ètò ààbò gbogbogbò – pẹ̀lú ìbámu pẹ̀lú òfin àti ẹ̀tọ́ ènìyàn.
10. Kikó owó jọ, kí a sì máa ṣàkóso Owó Ìdágbò Ààbò Ògbómọ̀ṣó pẹ̀lú òtítọ́ àti àfihàn àbájáde – kí gbogbo ọmọ Ògbómọ̀ṣó nílé àti ní òkè-òkun, àwọn ilé-iṣẹ́ àti àwọn olùfẹ́ Ògbómọ̀ṣó lèkópa.
ÌPÈ SÍ ÌṢẸ́
Ìpàdé náà ń ké sí gbogbo àwọn olùkópa àti ọmọ ile Ògbómọ̀ṣó láti kúrò nínú ìdáhùn sí ìṣòro lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í dènà ewu kí ó tó ṣẹlẹ̀.
Kí a kúrò nínú ìyàsọ́tọ̀, kí a sì gba ìfọwọ́sowọ́pọ̀laaye, Kí a kúrò nínú àìlera, kí a sì kọ́ agbára ìfaradà.
A gbọ́dọ̀ dá ètò ààbò kan sílẹ̀ tí: ìmọ̀ àti ìròyìn dá lé lórí; àwọn aráàlú ní imo nipa ohun tí wọ́n jẹ́;
àwọn ilé-iṣẹ́ àti ìjọba ń ṣiṣẹ́ pọ̀; àwọn aṣáájú ìbílẹ̀ ń kópa; tí ó sì ní ìṣàkóso tó hàn gbangba àti jíjẹ́wọ́ ojúṣe.
Ìpàdé náà parí pé ààbò ile Ògbómọ̀ṣó jẹ́ ojúṣe gbogbo wa, ó sì jẹ́ ohun tí kò ṣeé yà kúrò nínú ìmúṣẹ Ìran olodun marundinlogbon fún Ìdàgbàsókè Ògbómọ̀ṣó.
Nítorí náà, gbogbo àwọn olùkópa ni a rọ̀ láti yí àwọn ìpinnu ìpàdé yìí padà sí ìṣe gidi, ìṣe tí a lè díwọ̀n, tí ó sì lè wà fun igba pipẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ pàtàkì, èyítí ó di ìpìlẹ̀ ìpàdé náà:
“A GBỌ́DỌ ̀ DÁ ILÈ ÒGBÓMỌṢÓ NÍ ILÈ ÀÀBÒ KÍ ILÈ ÒGBÓMỌṢÓ LÈ DÌDE SÓKÈ.”
A gbé Ìkédé yìí jáde ní Ògbómọ̀ṣó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ yọ́, Nàìjíríà, ní ọjọ́ Ogbonjo Oṣù Kẹsàn-án, odun 2026.
_______________________________ _________________________________
DR. FEMI BABAJIDE REAR ADMIRAL JACOB AJANI (RTD)
Alága Ìgbìmọ́ Ìkédé, Alága ìgbìmo ìfilólè
You can get every of our news as soon as they drop on WhatsApp ...To get all news updates, Join our WhatsApp Group (Click Here)











